Journal of Indigenous Languages (JIL) - 2025 | http://journals.jozacpublishers.com/jil Vol. 3, No. 1, 2025 DOI: https://doi.org/10.5281/zenodo.17987700 Website: http://journals.jozacpublishers.com/jil Type of the Paper: (Journal Article) Àtúngbéyẹwò Ìlò Àti Ìṣesí Àwọn Ọrọ À-So-Ọrọ-Pọ Ní Èdè Yorùbá Olabode Thomas Abimbola1* 1*Department of Linguistics, African Languages & Communication Arts, Lagos State University (LASU), Ojo / Faculty of Arts, Lagos, Nigeria.
[email protected] / [email protected] ORCID: https://orcid.org/0009-0004-2580-8185 Correspondence: [email protected] Received: July 16, 2025; Accepted: September 23, 2025; Published: December 19, 2025 Àṣamọ: Ninú gírámà èdè Yorùbá, àwọn onímọ gírámà ṣe àkíyèsí pé àwọn ọwọ ọrọ kan wà tí wọn máa ń lò láti fi so ọrọ, àpólà tàbí gbólóhùn méjì pọ. Ẹnu kò lórí ọrọ-àsopọ ti ẹyọ ọrọ àti àpólà. Bí ó tilẹ jẹ pé ọwọ àwọn onímọ kan náà tilẹ sọ pé kò sí ohun tí a lè pè ní ọrọ àsopọ tí ó ń so gbólòhùn pọ, àwọn onímọ mìíràn sì gbà pé ó wà. Ohun tí a fẹ tẹpẹlẹmọ náà ni láti ṣàgbéyẹwò ìlò ọkọọkan àwọn ọrọ- àsopọ wọnyí, kí a mọ iye wọn, àti àwọn òté tó de ìlò wọn nínú èdè Yorùbá. A ṣe àkójọ àwọn détà lóríṣìíríṣìí láti inú àwọn onírúurú ìwé ti wọn kọ lédè Yorùbá àti ọrọ ẹnu àṣàyàn àwọn tí ń sọ èdè Yorùbá. A kò ṣàmúlò tíọrì kankan nínú iṣẹ yìí kí a lè walẹ jìn lórí àpèjúwe ìṣesí àtì ìhùwàsí àwọn ọrọ- àsopọ wọnyí. Ohun tí a ṣe ni pé, a ṣàpèjúwe ìlò àti ìṣesí àwọn ọrọ-àsopọ ni. A rí i pé ọrọ-àsopọ Yorùbá wà ní abẹ ìsọrí wúnrẹn aṣegírámà nítorí àwọn àbùdá ìsọrí náà tó pinminrin sínú rẹ. Bí a bá gùnlé ìlò àti ìṣesí wọn, a lè pín ìsọrí ọrọ-àsopọ Yorùbá sí ọwọ méjì gbòòrò: àkọkọ ni ọrọ-àsopọ tí ó pín sí i: ọrọ a-so-ọrọ/àpólà-pọ àti ọrọ a-so-gbólóhùn-pọ. Èkejì ni ọrọ-a-so-èjì-èrò-pọ tàbí ọrọ-asojú-sòdì-pọ/elérò ajárètí, ìsọrí yìí náà pín sí: alábala méjì àti aláwẹ kan. Kókó-ọrọ: Ìsesí, Ọrọ-àsopọ, Òté-ìlò, Wúnrẹn aṣegírámà, Yorùbá Abstract: In Yoruba grammar, scholars have noted that there is a class of words which are used to connect words, phrases, and sentences together. Scholars seem to agree on the presence of lexical and phrasal conjunctions. Despite the fact that some scholars opined that there is nothing like a sentence conjunction in Yoruba, some scholars agreed that there is a sentence conjunction in the language. This work is not concerned with arguments about argument on the presence of sentence conjunctions or not. The main concern of the present work is to re-examine how each connective/conjunction is used, how many of them are used in numbers, and their usage constraints in the grammar of the Yoruba language. Syntactic structures are collated from various grammar texts and books written in the Yoruba language. No grammatical theory is adopted so as to give a detailed description of connective items’ syntactic behaviours in actual usage. It was discovered that conjunction is a subclass of functional items based on the prepondrance of grammatical features found in the words. If usage and syntactic beahviour are used as classifactory features, Yoruba connective items can be classified into two broad categories: the first is the conjunction which is sub-classified into lexical/phrasal conjunction and sentence conjunction. The second one is disjunction which is subclassified into: bi-structural and uni-structural disjunctions.
Journal of Indigenous Languages (JIL) 173 of 185 Keywords: Conjunction, Grammatical item, Syntactic behaviour, Usage constraints, Yorùbá 1. Ìfáárà Àwọn àpẹẹrẹ ìhun gbólóhùn tó wà ní (1a-d) ní ìsàlẹ yìí, àwọn ọrọ kan wà tí a kọ níbùú àti ní àkọhàn oníbùú, a máa ń lò wọn gẹgẹ bí ọrọ tí a fi ń so ọrọ tàbí ìhun méjì pọ (Awobuluyi, 1978; Yusuf, 1999; Bamgbose, 1990; Yusuff, 2006 àti àwọn mìíràn). 1a) Ọlá àti/pẹlú Fọlá jẹ ọrẹ b) Òkùnrin dúdú náà àti/pẹlú àwọn èèyàn rẹ dúró de àlèjò pàtàkì d) Ní ọla àti/pẹlú ní ọtunla ni aputupu ó hu Àwọn ọrọ náà yàtọ ní ìṣesí àti ìtumọ wọn sí àwọn ọwọ tí a rí nínú ti ìsàlẹ wọnyí: 2a) Tọlá fẹràn ẹgbọn rẹ ṣùgbọn/àmọ Lọlá fẹràn àbúrò rẹ b) Adé kúrú, ó sì sanra Ohun tí àwọn onímọ fi yé wa ní pé, àwọn ọrọ tí a kọ ní àkọhàn wọnyí jẹ ọrọ-àsopọ. Bẹẹ sì ni pé, ìṣesí àti ìhùwàsí wọn nínú ìhun kò jọra. Àwọn onímọ kan gbà pé a lè so ọwọ àwọn ọrọ kan pọ láìlè so àwọn ọrọ mìíràn pọ pẹlú ọrọ-asopọ. Bẹẹ sì ni pé a máa ń ka gbogbo àwọn ọrọ náà sí abẹ ìsọrí kan náà. Púpọ nínú àwọn onímọ ni wọn ti ṣe akitiyan ní oríṣìíríṣìí láti sọ nípa àwọn ọrọ-àsopọ wọnyí. Ṣùgbọn, nínú iṣẹ yìí, ohun tí ó jẹ àwa lógún gan-an ni láti ṣe àtúngbéyẹwò àwọn ọrọ-àsopọ wọnyí láti mọ ìlò wọn, ìṣesí wọn, ọwọ tàbí ìpínsísọrí tí a lè kà wọn sí àti láti ṣàpèjúwe wọn bó tí tọ. Ìdí ni èyí tí a fi fẹ mọ ìdáhùnsí àwọn ìbéèrè iṣẹ ìwádìí yìí. A fẹ mọ bí ìṣesí, ìhùwàsí àwọn ọrọ-àsopọ ṣe rí ní èdè Yorùbá. Ṣé lóòtọ ni àwọn kan ṣeé pààrọ ara wọn láìfa ìyàtọ ìtumọ ìhun náà? Ǹjẹ gbobo wọn ni wọn jẹ ọrọ-àsopọ tabí àwọn kan ní ìsọrí mìíràn tó fara pẹ ti ọrọ-àsopọ? 2. Iṣẹ àwọn ẹni ìṣáájú Gẹgẹ bí ó ṣe hàn nínú iṣẹ àwọn onímọ, oríṣìíríṣìí ọnà ni àwọn onímọ gírámà ti gbà láti ṣàpèjúwe ọrọ- àsopọ àti láti ṣàtúnpín wọn sí ọwọọwọ. Ní abala yìí, a ṣàgbéyẹyò ìṣẹ àwọn ẹni ìṣáájú lórí ọrọ-àsopọ láti mọ ibi tí iṣẹ dé àti ibi tí iṣẹ kù sí. Awóbùlúyì (1978) ki ọrọ-àsopọ gẹgẹ bí ọrọ tí ó ń fi òye pé ọrọ méjì tàbí jù bẹẹ lọ jọ lọ pọ tàbí pé wọn ti di ọkanhùn. Ìyẹn ni pé, ọrọ-àsopọ máa ń so ọrọ méjì tàbí àlòpọ-ọrọ pọ tí yóò sì fi yéni pé ìtumọ irú ọrọ bẹẹ jọ lọ pọ tàbí pé wọn yóò jọ ní ìtumọ kan náà. Ó ya irúfẹ àwọn ọrọ bí “àti”, “pẹlú” sọtọ gẹgẹ bí ọrọ-àsopọ, ó sì fi ṣàlàyé pé wọn yàtọ ní ìtumọ àti òye sí ìbátan wọn ọrọ a-so-èjì-ọrọ-pọ tí a mọ sí “disjunction” ní Gẹẹsì. Ìyẹn ni pé, wọn jọ ara wọn ní irúfẹ ìṣesí-gírámà tó dá lórí àyè wọn nínú ìhun, àti síso nǹkan pọ. Nítorí náà, Awobuluyi (1978) fi ìdí rẹ múlẹ pé, Yorùbá kò ní ọrọ-àsopọ fún gbólóhùn lẹyìn tí ó tọka sí “sì” pé ó jẹ aláìfìwàjọ ọrọ-àsopọ. Nítorí pé àwọn onímọ ìṣáájú wòye pé, gbólóhùn ni ó máa ń wà ní iwájú àwọn ìhun náà ni wọn ṣe kà wọn sí ọrọ-àsopọ gbólóhùn. Wọn ń fi òye pé èrò méjì jẹ ojú-àti-òdì ara wọn. Ìyẹn ni pé, gbógbó wọn kì í ṣe ọrọ-àsopọ. Bí a bá tẹlé èrò Awóbùlúyì (1978) yìí, a lè pín àwọn ọrọ tó lè so ọrọ pọ sí ọwọ méjì nípa lílo àbùdá ìṣọwọso-ọrọ-pọ tàbí àbájáde ìtumọ ìsopọ náà: ọrọ-àsopọ àti ọrọ-a-so-èjì-èrọ-pọ. Àmọ Awobùlúyì (1978) náà ni ó sọ pé àwọn elédè máa ń lo ọrọ-àsopọ lọpọ ìgbà láti fi yálà ìbáṣepọ tàbí ìṣòdìsí/ìyapa hàn. Awóbùlúyì (1978:106) tọka àwọn wọnyí: “àfi/àyàfi”, “àmọ”, “ṣùgbọn”, “bóyá...àbí/tàbí”, “yálà...àbí/tàbí”, àti “ańbọọsí/ańbọtorí/ańbẹlèńté/ańbẹlètàsẹ”. Yusuf (1980) náà tọka sí èrò Stockwell et. al. (1973) pé elédè máa ń lo ọrọ àsopọ láti fi ìbáṣepọ ọrọ hàn. Irú ìbáṣepọ náà lè jẹ ti ìjọra (similarity), ìjọṣẹlẹ (simultaneity), ṣísẹ-n-tẹlé (sequentiality), abbl.
Journal of Indigenous Languages (JIL) 174 of 185 Èyí fi hàn pé, irú ọkanhùn ni wọn. Ọkan lára iṣẹ tí ọrọ-àsopọ ń ṣe ní ó hàn nínú ọrọ a-so-èjì-èrò-pọ. Ṣùgbọn, wọn yàtọ sí ọrọ-àsopọ gbólóhùn bíi ti “and” ní Gẹẹsì. Yusuf (198) náà tọka sí àwọn ọrọ wọnyí gẹgẹ bí ọrọ àsopọ lédè Yorùbá: àti, pẹlú, òun, àfi, àmọ, ṣùgbọn, bóyá...àbí/tàbí, yálà...àbí/tàbí, ańbọsí/bèlètàsé, síbẹsíbẹ, sì, bẹẹ ni. Bí a ṣe ń lo àwọn wúnrẹn ìyísódì wọnyí ni ó jẹ àwa lógún nínú iṣẹ yìí. Yusuf (1999) ki ọrọ àsopọ gẹgẹ bí ọrọ ti a fi ń so àpólà ọrọ tàbí gbólóhùn pọ. Oríkì yìí jọ ti àfimọ ti tíọrì gbé kalẹ nítorí pé nínú tíọrì olófin ìyídà, ẹyọ ọrọ lè ṣiṣẹ gẹgẹ bí àpólà orúkọ. Àmọ irú àpólà àti gbólóhùn tó ṣeé so pọ ni kò ṣàpẹẹrẹ rẹ fún wa. Èrò rẹ kò yàtọ sí ti Yusuf (1980) tí a ti mẹnubà ní ìṣáájú. Bámgbóṣé (1990: 189) ṣàlàyé pé “gbólóhùn alákànpọ ni èyí tí a fi ọrọ-àsopọ so àwọn gbólóhùn mìíràn pọ láti di ẹyọ kan”. Àmọ ṣá, kì í ṣe gbogbo ohun tí a bá fi ọrọ-àsopọ so pọ ni yóò ní ìtumọ kan. Bẹẹ sì ni pé kìí ṣe gbólóhùn nìkan ni a lè fi ọrọ-àsopọ so pọ nínú èdè Yorùbá. Bí ó tilẹ jẹ pé èrò yìí kò ki ọrọ-àsopọ gan-an, ó fún wa ní ìwòréré ìṣesí àwọn ọrọ-àsopọ. Ní ti Yusuff (2006: 37), ó ki ọrọ-àsopọ gẹgẹ “ọrọ tí ó ń so ọrọ pọ, so àpólà ọrọ pọ tàbí so gbólóhùn pọ”. Èyí dálé ọkan lára ìhùwàsí ọrọ-àsopọ àti irúfẹ nǹkan tó lè so pọ, tíí ṣe ọrọ, àpólà àti gbólòhùn. Bí a bá gùnlé oríkì ti Yusuff (2006) yìí, a ó kíyèsi pé kì í ṣe oríṣìí ọrọ-àsopọ kan ni ó wà látàri irúfẹ nǹkan tí wọn lè so pọ. Ó pín àwọn ọrọ-àsopọ sí ìsọrí pẹlú lílo àbùdá ìtumọ. Àwọn náà ni ọrọ-àsopọ oníjọra: àti/ti, pẹlú, òun. Ohun tí ó jẹ wọn lógún ni irúfẹ ìjọra tó wà núnú ìhun tí àwọn wúnrẹn àsopọ náà so pọ. Ṣùgbọn, wọn kò mẹnubà á pé ìjọra yìí kì í ṣe ti i rúfe àbùdá ọ rọ tí ó ń sọ ìhun méjè èjì pọ . ìtumọ ni wọ n gùnlé. Àti pé, gbogbo bí elédè ṣe lè lo àwọn wúnrẹn náà ni àlàyé kò jìnlẹ tó lé lórí. Ó tilẹ sọ pé àgékúrú “àti” ni “ti” jẹ. Àti pé ìtumọ àkànlò ni ó sáábà máa jẹ. oríṣìríṣìí àríyànjiyàn ni ó wà lórí “tí” ní èdè Yọrùbá bíi Awóbùlúyì (2008) àti àwọn mìírà n tí wọ n ti me nuba ọ rọ lórí re . Èkejì ni ọrọ-àsopọ oníyapa: “àyàfi/àfi”, “àmọ”, “ṣùgbọn”, “síbẹ”, “bóyá...tàbí/àbí”, “yálà...tàbí/àbí”, “ańbọsí/ańbèlètè/ańbọsìbọsí”. Àkópọ wà nínú ọwọ yìí. Bí a bá wo ìtumọ àwọn ọrọ wọnyí àti irúfẹ bí elédè ṣe ń lò wọn, yóò fojú hànde pé àkópọ lásán ni ó ṣẹlẹ níbí. Bẹẹ sì ni síbẹ gba àkíyèsí. Ọwọ kẹta ni ọrọ-àsopọ onítẹléǹtẹlé tíí ṣe sì. Ó ka “òun” sí ọrọ-àsopọ lòdì sí èrò Ìlọrí (2012) lóri “òun”. Bí ó tilẹ rí báyìí, àlàyé Yusuff (2006) fẹjú díẹ ju gbogbo àwọn yóòkù lọ àmọ kò tẹpelẹmọ ìṣesí àti ìhùwàsí nínú ìhun láti fi bí wọn ṣe rí hàn. Iṣẹ tí a fẹ ṣe ni àtúngbéyẹwò àti ìfẹlójú àwọn iṣẹ tó ti wà nílẹ àti láti tún mú èrò àti òye nípa àwọn ọrọ-àsopọ jinlẹ si. Ìlòrí (2010) ṣàgbèyẹwò ọrọ-àsopọ Yorùbá. Ọrọ àpọnlé aṣáájú ìṣe ni ó pè “sì”, tí “dẹ” jẹ ẹdà rẹ. Àlàyé rẹ dálé Tíọrì Oníwọba-Èròjà. Ó ní ìgbésíwájú ló fa kí ó máa jẹ yọ ní ibi tí ó ti ń jẹyọ. Ó gbà pé kò sí ọrọ-àsopọ tí ó dàbí “ṣùgbọn/àmọ” tí a lè pè ní ọrọ-a-so-gbólóhùn-pọ nínú èdè Yorùbá ní ìbámu pẹlú Awóbùlúyì (1978). Ìlọri (2012) wòye pé “òun” kì í ṣe ọrọ-àsopọ gẹgẹ bí ìmọ àtijọ ti fi hàn wá. Iṣẹ rẹ gan-an ni awẹyìn tí ó ń tọka sí ọrọ-orúkọ ìṣáájú. A faramọ èrò yìí nítorí pé kò sé, kò yà sí “òun” tíi ṣe ọrọ-arọpò orúkọ gígùn. Nítorí náà, “òun” kò sí lára àwọn ọrọ-àsopọ wọnyí. Abimbola (2015 ) ṣàgbéyẹwò èrò àtijọ lórí ọrọ-àsopọ. Ó dálé àríyànjiyàn tó wà lórí “sì”, pé ṣé èdè Yorùbá ní ọrọ-àsopọ ti gbólóhùn àbí kò sí? Awóbùlúyì (1978) ti kọkọ ṣe àlàyé pé kò sí. Ṣùgbọn púpọ nínú àwọn onímọ gírámà bí Yusuff (2006), Ilori (2010), Abimbola (2015) àti àwọn mìíràn ni wọn gbà pé “sì” jẹ ọrọ-àsopọ. Èrò Abimbola (2015) ni pé, “sì” pé oríṣìí nínú èdè Yorùbá: sì atọka ìtẹnumọ, sì atọka ìṣẹlẹ ṣísẹ-n-tẹlé, sì tíi ṣe ọrọ-àsopọ. Yàtọ sí àwọn mẹta yìí, ó ní èdè Yorùbá ní ọrọ-àsopọ gbólóhùn onírìísí afarasin nínú àwọn gbólóhùn tí “sì” ti ń ṣiṣẹ gẹgẹ bí ìtẹnumọ tàbí ìṣẹlẹ ṣísẹ-n-tẹlé. Adékẹyè (2016) náà kí ọrọ àsopọ gẹgẹ bí wúnrẹn tàbí ọrọ tí ó ń só ẹyọ ọrọ, àpólà, tàbí odidi gbólóhùn pọ. Ṣùgbọn, èrò rẹ kò yàtọ sí àwọn àlàyé tó ti wà tẹlẹ. Abimbola (2024) náà fi kun pé ọrọ- àsopọ náà jẹ ọkan lára àwọn ọrọ aṣegírámà tàbí wúnrẹn aṣegírámà nítorí láìlò ó nínú ìhun a kò lè mọ
Journal of Indigenous Languages (JIL) 175 of 185 ohun tó túmọ sí bí àwọn ọrọ bí ọrọ-ìṣe, ọrọ-orúkọ, àti àwọn mìíràn. Bí ó tilẹ jẹ pé a ti wo ọpọlọpọ àwọn oríkì kan tẹlẹ, kò sí èyí tó tọka sí àbùdá kan tí ìsọrí ọrọ-àsopọ ní bí ó ṣe hàn nínú oríkì yìí: ọrọ- àsopọ ni irúfẹ àwón ọrọ aṣegírámà tí wọn ń fi so ọrọ, àpólà, gbólóhùn méjì tàbí jù bẹẹ lọ pọ láti fi wọn hàn pé wọn ṣe ọkan ní èrò (Abimbola, 2024). Àbùdá kan tó ya ìsọrí ọrọ-aṣegírámà sọtọ ni pé a kò lè ṣẹdá ọrọ lára wọn tàbí kí a fi kún wọn nínú èdè bí a ti lè ṣe fún ọrọ-orúkọ àti ìsọrí àwọn ọrọ mìíràn. A kò lè fi kún ọrọ-àsopọ èdè Yorùbá, nítorí náà. A ó wo àwọn àbùdá tó sọ ọrọ-àsopọ di wúnrẹn tàbí ìsọrí ọrọ-aṣegírámà. 3. Ọgbọn Ìṣèwádìí A ṣe àmúlò àwọn fọnrán gbólóhùn tí ó ti wà nílẹ tẹlẹ nínú àwọn ìwé gírámà. A tún ṣàmúlò àwọn ìhun gbólóhùn tí a ti tò jọ fún àyẹwò ní onírúurú fún àkojọ dáta wa. Èròǹgbà wa ni pé bí a bá lè ṣàpèjúwe wọn dáadáa, òye nípa wọn yóò túnbọ jinlẹ ju tàtẹyìnwá lọ. 4. Ọrọ-àsopọ Yorùbá gẹgẹ bí wúnrẹn aṣẹgúir ámà Gẹgẹ bí a ti mẹnu bà á lókè pé Abímbọlá (2024) tọka pé ọrọ-àsopọ jẹ ọwọ ìsọrí aṣegírámà, wúnrẹn aṣegírámà ni ọwọ àwọn ọrọ tí wọn ní ìtumọ gírámà (tàbí èyí tí kò ní ìtumọ kankan), yàtọ sí àwọn ìsọrí-ọrọ aláìnítumọ gírámà tí wọn ní ìtumọ kíkún tí a lè tètè mọ (McIntyre, 2015:1). Ìyẹn ni pé láìmú wọn lò nínú ìhun gbólóhùn, kò ṣeé ṣe kí a lè tètè tọka ìtumọ tí àwọn wúnrẹn aṣegírámà ní. Ó tọka àwọn ọrọ bíi atọka aṣàfihàn, ọrọ-àsopọ, atọka amúpé àti àwọn yòókù. Èyí fi hàn pé ọrọ-àsopọ jẹ ọkan lára wọn bí a bá wo ìṣesí wọn ní ìbámu pẹlú oríkì wúnrẹn aṣegírámà òkè yìí. Bákan náà ni Rizzi àti Cinque (2016) sọ pé ìyàtọ àwọn ọrọ aṣegírámà àti ọrọ aláìṣegírámà yàtọ sí níní ìtumọ ajẹmọgírámà tí ó sábà máa ń jẹ mọ afòyemọ ni pé, àwọn ọrọ tàbí wúnrẹn aṣegírámà sábà máa ń ní: i) Ìhun/ìrísí fonọlọjì tó yàtọ. Àwọn ọrọ-àsopọ èdè Yorùbá máa ń sábà bẹrẹ pẹlú ìró kọńsónáǹtì. Púpọ nínú wọn ni wọn jẹ oní-sílébù méjì. Èdè Yorùbá ní ọwọ àwọn tí wọn jẹ ẹlẹlà bí a bá wo ìhun wọn tí abala ìhun tí wọn ń so pọ yóò sì wà láàárín. ii) Iye tó ṣeé kà nínú èdè. A kì í lè fi kún iye wọn nínú èdè. Bí iye àwọn ọrọ-àsopọ ṣe rí ní èyí fi hàn. A kò lè fi kún iye wọn ní èdè Yorùbá. iii) Àìlèṣẹdá ọrọ tuntun láti ara wọn. Ó jẹ àbùdá pàtàkì tí ó tún fi wọn hàn gẹgẹ bí wúnrẹn aṣegírámà nítorí a kò lè ṣẹdá ọrọ lára wọn. “Àti/ti” ni a sábà máa ń lè kànpọ pẹlú ọrọ-orúkọ ní èdè Yorùbá. yàtọ sí èyí tí a tọka yìí, ṣíṣẹdá ọrọ láti ara ọrọ-àsopọ Yorùbá kò ṣeé ṣe. iv) Wọn a máa ṣokùnfà gbígbé ọrọ síwájú nínú ìhun. Bí wọn bá ní àwọn àbùdá tó yẹ làti fi gbé ọrọ láti ibi kan sí ìbòmíràn, bíi ìtẹnumọ, àsọdọtọ, abbl, wọn á fa gbígbé ọrọ tàbí fọnrán-ìhun náà. Èyí ṣeé ṣe nígbà tí a bá tẹnumọ àpólà orúkọ alásopọ ní èdè Yorùbá. v) Wọn máa ń fa ìyípadà tàbí ìyàtọ ajẹmọ-ẹka-èdè nínú ìhun gírámà. Ní ọpọọgbà ni ó jẹ pé ìyàtọ ajẹmọhùn gíràmà máa ń wáyé tí ó sì jẹ pé àwọn wúnrẹn aṣegírámà ni ó máa ń ṣokùnfà wọn. Kódà, wọn lè mú kí ẹka-èdè kan yàtọ sí èkejì. Nínú àwọn ẹka-èdè Yorùbá kan ní a ti sábà máa ń bá àwọn ọrọ bíi “ańbẹlète”, “ańbèlètàsé”, abbl. pàdé. Bí a bá wo àwọn àbùdá wọnyí, a ó rí pé òótọ ni pé ọrọ-àsopọ èdè Yorùbá jẹ ìsọrí wúnrẹn aṣegírámà. Àfijọ kan tí àwọn wúnrẹn aṣegírámà ní pẹlú àwọn ìsọrí-ọrọ aláìṣegírámà ni pé wọn jọ máa ń jẹ oríìhun. Ọrọ-àsopọ lè jẹ orí-ìhun alásopọ nínú gírámà èdè Yorùbá. Àwọn onímọ tíọrì bíi ti tíọrì Oníwọnba Èròjà sábà máa ń tọka sí èyí. Ó tilẹ fẹẹ jẹ pé gbogbo ìhun ni ó ní wọnrẹn aṣegírámà tó gàbà lé wúnrẹn aláìṣegírámà ní ọnà kan tàbí òmíràn. Àmọ, iṣẹ ti wa kò ní nǹkan ṣe pẹlú tíọrì kankan bí kò ṣe pé kí a ṣe àlàyé ìṣàpèjú bí a ṣe ń lò wọn.
Journal of Indigenous Languages (JIL) 176 of 185 Àtúnpínsísọrí ọrọ-àsopọ Ní abala yìí, ohun tó jẹ wá lógún ni láti yànnàná àwọn ọwọ tí a lè pín onírúurú àwọn ọrọ àsopọ sí fún ìṣàpèjúwe wọn. Oríṣìí ọnà ni a lè gbà pín àsopọ Yorùbá. Bí a bá gùnlé ohun tí wọn ń so pọ tàbí ìhunìsopọ gẹgẹ bí òṣùwọn tàbí àbùdá ajẹmọhun láti ṣàtúnpín wọn sí ọwọọwọ, a lè pín wọn sí ọwọ méjì: i) Ọrọ a-so-ọrọ-orúkọ/àpólà-pọ: àwọn wọnyí ni a ń lò láti fi so ẹyọ ọrọ/ọrọ orúkọ, ọrọ-arọpò orúkọ gígùn, àpólà orúkọ, àti àpólà àtọkùn pọ. Èyí ni ọrọ-a-so-ọrọ-orúkọ-pọ tàbí ọrọ-a-so-àpólàpọ. A ṣe àpèjúwe rẹ ní ìsàlẹ. Àpẹẹrẹ ni: “àti/ti” àti “pẹlú”. ii) Ọrọ a-so-gbólóhùn-pọ: gẹgẹ bí orúkọ rẹ, èyí ni àwọn ọrọ-àsopọ tí a ń lò láti fi so gbólóhùn pọ nínú èdè Yorùbá. A ṣe àpèjúwe wọn ní ìsàlẹ. Àpẹẹrẹ ni: sì, àti ọrọ-àsopọ onírísí afarasin. Bí a bá gùnlé àbájáde ìsopọ, ìṣọwọso-ọrọ-pọ tàbí àbájáde ìtumọ ìsopọ gẹgẹ bí òṣùwọn tàbí àbùdá, a lè pín àwọn ọrọ tó ń so ọrọ tàbí ìhun méjì pọ sí ọwọ méjì: i) Ọrọ-àsopọ (conjunction): Ọrọ-àsopọ ni àwọn wúnrẹn aṣegírámà tí a ń lò fi so ọrọ méjì, àpólà tàbí gbólóhùn méjì pọ láti fi hàn pé àbáyọrí ìtumọ àti ìhun wọn ṣe ọkan. Ọpọlọpọ àwọn wọnyí ni wọn wà nínú èdè Yorùbá láti so ẹyọ ọrọ méjì, àpólà orúkọ, àpólà atọkùn àti gbólóhùn pọ. ii) Ọrọ a-sojú-sòdì-pọ (disjunction): Ìbátan ọrọ-àsopọ ni ọwọ kejì yìí jẹ sí ọrọ-àsopọ. Àwọn wọnyí kò tí ì ní àpèjúwe tí ó tọ bó ti yẹ nínú àwọn ìwé gírámà ju kí wọn máa pè wọn ní ọrọ- àsopọ lọ. Wọn máa ń dúró sáàárín ìhun méjì tí wọn ń so pọ tàbí kí wọn dúró ní ìbẹrẹ abala ìhun tí a fẹ so pọ tí awẹ kan yóò sì jẹ mọọn-nú látàrí ìmọtẹlẹ tí àtolùgbọ àtolùsọ ti ní tẹlẹ. A tún lè pè wọn ní àwọn ọrọ a-so-èjì-èrò-pọ bí “ṣùgbọn”, “àmọ”, “àfi/àyàfi”. Bí a bá wo ìrísí tàbí mọfọlọjì àwọn ọrọ-àsopọ àti ọrọ asojúsòdìpọ gẹgẹ bí òṣùwọn, a lè pín gbogbo wọn sí ọwọ méta: i) Ọrọ-àsopọ aláwẹ-kan: Àwọn wọnyí ni ọrọ-àsopọ bí “àti/ti”, “pẹlú”, “àmọ”, “sì” tí wọn ní awẹ kan ṣoṣo. Wọn kò ṣe é là sí méjì. ii) Ọrọ asojúsòdìpọ aláwẹ-ìhun kan/alábala kan: Àpẹẹrẹ àwọn ọrọ asojúsòdìpọ aláwẹ kan ni “ṣùgbọn” àti “àmọ”, “ańbọsí/ańbọtorí/ańbèlètàsé/ańbọsìbọsí” àti “síbẹsíbẹ”. Wọn sì máa ń dúró láàárín wúnrẹn méjì tí wọn ń so pọ. iii) Ọrọ-àsopọ aláwẹ-méjì/alábala-méjì: Àpẹẹrẹ àwọn wọnyí ni: “yálà...tàbí/àbí”, “bóyá...tàbí/àbí”, Àbùdá ajẹmérò: Bí a bá gùnlé èrò, a lè wò ó pé ṣe èrò náà ṣọkan tàbí èrò náà jẹ alójú-lódì tàbí oníyíyan èrò kan péré. Bí a bá wo ìye èrò tó wà nínú ìhun tí a ní a lè pin sí: i) Elérò aṣọkan: Èrò kan péré ni àwọn wọnyí ń ṣàfihàn. ii) Elérò atakora tàbí alójúlódì: èrò méjì tí wọn jẹ òdì ara wọn ni àwọn wọnyí ń ṣàfihàn iii) Oníyíyan èrò kan: Àwọn wọnyí jẹ mọ yíyan èrò kan péré nínú méjì tó wà nílẹ. Àbùdá ajẹmọ-ìlò: Èyí ni ọnà tí a gbà lo àwọn ọrọ-àsopọ gẹgẹ ọnà láti pín wọn sí ìsọríìsọrí. Bí a bá gùnlé àbùdá yìí, a lè pín sí i) Oníyíyàn: O gbà pé kí a yan ọkan nínú ohun tí ó wà nílẹ. ii) Aláìgbayíyàn: Èyí kò fàyè gba yíyàn láàárín ohun méjì. Ní abala tó kàn ni a ti ṣe àpèjúwe ìlò ìkọọkan àwọn ọrọ àsopọ àti ọrọ asojúsòdìpọ láti lè fa òté tí ó de ìlò wọn yọ.
Journal of Indigenous Languages (JIL) 177 of 185 Ọrọ- A-so-ọrọ-orúkọ-pọ tàbí Ọrọ-a-so-àpólà-pọ Èyí ni àwọn ọrọ-àsopọ tí wọn ń so ọrọ-orúkọ, ọrọ-arọpò orúkọ gígùn, àpólà orúkọ àti àpólà àtọkùn pọ. Ní àkọkọ, bí a bá yọ ọwọ “òun” kúró nínú wọn, yóò ku méjì péré: “àti” àti “pẹlú”. Bí ó ti lẹ jẹ pé ọrọ tàbí àpólà ni a fi ń so pọ, a kì í fi so ọrọ-arọpọ-orúkọ kúkúrù, ọrọ-ìṣe, àpólà ìṣe, ọrọ-àpejúwe, ẹyán, ẹpọn àti àwọn wúnrẹn aṣegíràmà pọ ní èdè Yorùbá. Ọwọ yìí ni ìsọrí àwọn ọrọ-àsopọ tàbí a-so-ọrọ- pọ tí wọn máa ń lò báyìí. i) Ọrọ-orúkọ + ọrọ-orúkọ (OR+OR): A lè èyíkéyìí nínú àwọn àti àti pẹlú láti fi so àwọn ọrọ orúkọ méjì pọ. A ṣàfihàn wọn ní ipò olùwà, àbọ-ọrọ-iṣe àti àbọ ọrọ-atọkùn ní ìhun oníbùú. Àpẹẹrẹ: 3a) Bọlá àti Ọlá ra ilé kan b) Wọn rí ọkọ àti aya ní ibẹ d) Olú ra bàtà fún Ayọ àti Dàda 4a) Tọlá pẹlú Lọlá jẹ ọmọ gidi b) Mo ní Bàbá pẹlú Ìyá d) Mo rà á fún Tolú àti Ẹrín ii) Ọrọ-arọpò orúkọ gígùn + ọrọ-arọopò-orúkọ gígùn (AROG +AROG): àwọn ọrọ-àsopọ wọnyí tún lè ṣiṣẹ gẹgẹ bí àsopọ fún ọrọ arọpò orúkọ gígùn méjì. Gbogbo àwọn AROG yìí jẹ mẹfà. Àbùdá ẹni àti iye ni a lè fi dá wọn mọ tí wọn fi farajọ àwọn ọrọ-arọpò orúkọ kúkúrú. Ṣùgbọn, wọn yàtọ sí AROG pẹlú àbùdá ìtẹnumọ tíí ṣe apàlà wọn (Abimbola, 2019). 5a) Ẹyin àti èmi ni a jẹ tẹtẹ náà b) Wọn sọrọ nípa ìwọ àti èmi d) Àwọn òṣèré náà yóò pidán fún ẹyin àti àwa ní alẹ 6a) Ẹyin pẹlú òun náà ni wọn sọ b) Wọn kìlọ fún àwọn pẹlú àwa d) Ó fẹ bá èmi pẹlú ẹyin ṣeré iii) Ọnà kẹta tí a tún lè gbà lò wọn ni a lè pín sí méjì bí a ṣe fi hàn ní ìsàlẹ yìí: a) Ọrọ-arọpò orúkọ gígùn + ọrọ-orúkọ (AROG+OR): A lè lo àwọn ọrọ-àsopọ náà nípa síso ọrọ- arọpọ-orúkọ gígùn pọ mọ ọrọ-orúkọ. Níbi tí AROG yóò ti ṣáájú tí ọrọ-orúkọ yóò tẹle. Àpẹẹrẹ; 7a) Àwa àti/pẹlú Ayọ san owó wa b) Bàbá rí ẹyin àti/pẹlú Adé d) Wọn sọrọ sí èmi àti/pẹlú Olú b) Ọrọ-orúkọ + ọrọ-arọpò orúkọ gígùn (OR+AROG): Yàtọ sí fífi àti tàbí pẹlú so ọrọ pọ bí a ṣe rí lókè yìí, ọrọ-orúkọ lè ṣáájú kí a sì so pọ mọ ọrọ-arọpọ-orúkọ gígùn. 8a) Adé àti/pẹlú òun ní ó dára b) Ṣé mo sọrọ burúkú sí Ṣọlá àti ìwọ ní àná d) Ó rí Adé Àkànkẹ àti/pẹlú èmi ní ìrònà iv) Àpólà atọkùn + àpólà atọkùn (APAT +APAT): Yatọ sí àpólà orúkọ ní sísopọ, àpólà atọkùn méjì náà lè di síso pọ pẹlú lílo àti tàbí pẹlú. Ọrọ-àsopọ náà yóò dúró sáárín àpólà atọkùn méjì náà. Àpẹẹrẹ; 9a) Wọn gbé orọ ní àdúgbò wa ní àná àti/*pẹlú ní ìjẹta b) Ní pàlàbà àti/*pẹlú ní bọrọgidi ní gbẹ àwọn igi náà
Journal of Indigenous Languages (JIL) 178 of 185 v) Ọnà mìíràn tí a tún lè gbà lo àti àti pẹlú ni kí a ka ọrọ-orúkọ ní ọwọọwọ tí yóò wá jẹ pé èyí tó kẹyìn ni a o fi ọrọ-àsopọ náà sí níwájú. Àpẹẹrẹ; 11a) Mo ra ilá, ẹgúsí, ata àti pọnmọ b) Ìsọrí ọrọ ni ọrọ-orúkọ, ọrọ-ìṣe, ẹyán, àti ìyísódì d) Èmi, ìwọ, òun àti ẹyin ni wọn dárúkọ e) Bàbá, ìyá, ọmọ, ará, àti ojúlùmọ wà ní gbàgede ẹ) Bọlá, tọlá, Fọlá àti èmi wà ní agbo náà. g) Fọlá ra bàtà, aṣo, àpò àti nǹkan ọbẹ mìíràn Ọwọ àwọn ìsọrí tí a tò jọ sókè wọnyí nìkan ni wọn ń so pọ. Gẹgẹ bí a ti sọ ní ìṣáájú, ọrọ-ìṣe, ọrọ- atọkùn, wúnrẹn aṣáájú-ìṣe, ọrọ-àpèjúwe, ẹyán, wúnrẹn ìyísódì, àti àwọn aṣegbólóhùn ni a kì í fi àwọn ọrọ-àsopọ méjèèjì wọnyí so pọ. Ní ti ìtumọ, àwọn méjèèjì ni wọn ń ṣàfihàn ìbáṣepọ láàárín ọrọ méjì tàbí jù bẹẹ lọ gẹgẹ bí ìṣesí ọrọ- àsopọ. Ṣùgbọn ó dà bí pé “pẹlú” kì í ṣe lò bi ti “àti” ní àwọn sàkánì kan náà. Gẹgẹ bí àpẹẹrẹ: • A lè lo àti láti fún wa ní ìtumọ onítẹnumọ-ṣísẹ-n-tẹlé. Ìyẹn ni pé, ìtẹnumọ máa ń farahàn ní ṣísẹ-n-tẹlé. Ní irú ìlò yìí, àwọn elédè Yorùbá sábà máa ń kan ọrọ-àsopọ “àti” mọ ọrọ-orúkọ. Gẹbẹ bí àpẹẹrẹ: 11a) Àtèní, àtọla, àtọjọ gbogbo ni elédùmarè yóò máa wà. b) Àtàná, àtòní, àtọla kò sí ìyàtọ. d) Àtọkọ, àtaya ni wọn kó riyẹriyẹ lọ. e) Àtitàná, àtitòní ni mo máa gbà lọwọ rẹ. ẹ) Àtèmi, àtìwọ, àtòun ni a gbọdọ ṣe ara-wa lọkan. Ṣùgbọn kò dàbí pé a lè lo “pẹlú” bẹẹ gẹgẹ bí àwọn gbólóhùn kòbẹgbẹmu ìsàlẹ wọnyí ti fi hàn. 12a) *pẹlánàá, pẹlónìí kò sí èyí tó ṣẹyìn mi b) ?pẹlọkọ pẹláya náà dáa. • A lè lo àti láti fi ìtumọ alálòpọ hàn tí “pẹlú” kò sì ṣe é lò bẹẹ. Àpẹẹrẹ: 13a) Àti arúgbó àti omidan ń kùlùbọ ìdí. b) Àti ọkùnrin àti obìnrin ni wọn máa ń kópa nínú ọdún náà. d) *Pẹlú arúgbọ pẹlú omidan ń kùlùbọ ìdí • Ó dà bí pé “pẹlú” ń ṣiṣẹ gẹgẹ bí ọrọ atọkùn. 14a) Bàbá pẹlú àwọn àbúrò rẹ ni ọrọ kàn. Mo pẹlú wọn nígbà tí wọn ń sọrọ. b) Wọn sọrọ kan pẹlú bàbá náà nípa ọmọ náà. d) Wọn rí ọmọ náà pẹlú òkú àdìyẹ lẹgbẹẹ ọnà. • A sábà máa ń lo “àti” fún ìsọdorúkọ láti ṣẹdá ọrọ-orúkọ tuntun. Ṣùgbọn kò dájú pé a lè lo “pẹlú” bẹẹ. Dípò bẹẹ, a lè fi “pẹlú” sí iwájú àwọn ọrọ tí a ṣẹdá látara “àti”. 15a) àtijẹ, àtimu, àtiná, àtilò b) pẹlú àtijẹ, pẹlú àtiná, pẹlú àtilò b) *pẹlújẹ,
Journal of Indigenous Languages (JIL) 179 of 185 • A lè lo àti pẹlú ìsọdorúkọ tí a lo pé láti ṣẹdá. ṣùgbọn kò dá pé a lè lo pẹlú bi èyí láìfa pé kí olùgbọ máa rò pé aláìgbédè ni olùsọ. Gẹgẹ bí àpééré: 16a) àti pé o lọ, àti pé o ò lọ kò kàn mí b) àti pé wọn rán àpò náà àti pé wọn ò rán, bí ó bá sọnù, ìwọ ni wọn ó mú. d) àti pé o ò ní sí ń bẹ kò da nǹkan kan. e) *pẹlú o lọ, pẹlú o ò lọ kò kàn mí Àkíyèsí kan tí ó wà nínú èyí ni pé, bí ẹni gbé gbólóhùn alápòólà orúkọ atakora méjì sẹgbẹẹ ara wọn ni ó rí. A lè lo awẹ kejì láfi awẹ àkọkọ sí iní ìhun náà, àmọ gbogbo awẹ kejì ni ó gbọdọ jẹ ìhun ìyísódì. • Àti ni a sáábà máa ń lò nínú ìkàlọwọọwọ ọrọ-orúkọ. Ìyẹn ni pé bí a bá ń dárúkọ ọrọ-orúkọ ní ìkọọkan, a lè lo “àti” láti fi so gbogbo wọn pọ. Gẹgẹ bí àpẹẹrẹ: 17a) Ìrẹsì, ẹyin, ata, àti ẹran b) Àga, tábìlì, pẹpẹ, àti igi • A máa ń lo “àti” nínú ìhun awẹ-ìsopọ nínú àpólà orúkọ. Ìyẹn ni pé, mọọn-nú ni awẹ tàbí abala tí a gé kúrò yóò jẹ fún àtolùgbọ àtolùsọ. 18a) Àtèmi náà ni wọn ń sọ b) Àti gbogbo ìlú ni wọn pẹ sí ibi ayẹyẹ náà. d) Àti ààrè ni wọn yẹ sí. Gbogbo àkíyèsí àti àpèjúwe yìí ni ó fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni a lè lo “àti” àti “pẹlú” gẹgẹ bí pàṣípààrọ ara wọn tàbí kí a sọ pé gbogbo ìgbà kọ ni a lè lò wọn gẹgẹ bí àrọ-ọrọ fún ara wọn láìpàdánù ìtumọ ìhun náà. Ṣùgbọn, “àti” ni a lè lò fàlàlàfalala bí ó ṣe wù wá. Tàbí “Tàbí” dàbí “ṣùgbọn/àmọ” ni. Ohun tí ó yà á sọtọ sí wọn ni pé kì í so èrò inú gbólóhùn pọ. Èyí tàbí ìyẹn ni ó máa ń fi hàn. Ìyẹn ni pé, ìlò rẹ jọ “àti/pẹlú”, òun kàn ń fi ìlò yíyan ọkan nínú ohun méjì tí ó lè jẹ ọrọ-orúkọ, àpólà orúkọ, àpólà atọkùn, àti AROG tí ó bá dúró láàárín wọn. Kì í ṣe pé òye sísopọ gan-an ni tirẹ, tirẹ ni pé èèyàn kò le è mú ohun méjì náà pọ àfi ọkan. Èyí ni pé “yan ìkan nínú ohun méjì náà” ni ìtumọ rẹ. Àpẹẹrẹ: 19a) Ilé tàbí owó b) Èyí tàbí ìyẹn d) Ipò tàbí ọlá 20a) Ìwọ tàbí èmi b) Àwa tàbí àwọn 21a) Bàbá àgbà tàbí ọkùnrin dúdú náà máa sọrọ lórí ọrọ náà. b) Agbádá ńlá tàbí ẹsikí fẹrẹgẹdẹ ni mo máa wọ wá. d) Ọkọ bọgìnnì tàbí ọkọ akérò e) ìyá arúgbó tàbí ọmọbìnrin ọpẹlẹńgẹ 22a) Ní àná tàbí ní òní
Journal of Indigenous Languages (JIL) 180 of 185 b) Ǹjẹ ìwé náà wà fún àwọn ọdọ tàbí fún àwọn màjẹsín? d) Fi òògùn náà sí ojú tàbí sí imú Ọrọ àsopọ yìí náà ní àwọn òté tó de ìlò rẹ nínu ìhun gírámà èdè Yorùbá. • Òté àkọkọ ni ó níí ṣe pẹlú ìtumọ ohun tí àsopọ yìí ń ṣe. Ìyẹn ni pé, ó ń ṣàfihàn ohun méjì tí kò ṣe é gbà pọ tàbí tí kò ṣe é yàn pọ lẹẹkan ṣoṣo. Ọkan ni èèyàn gbọdọ yàn nínú nǹkan méjèèjì náà tí ó pàtẹ rẹ. • Bí ìṣesí àti ìtumọ rẹ ti jọ “ṣùgbọn/àmọ” tó, kì í so gbólóhùn pọ. Ọrọ-orúkọ, àpólà orúkọ tàbí àpólà atọkùn ni ó máa ń so pọ bíi ti “àti/pẹlú”. • Àárín ìhun méjì tí o ń só pọ náà ni ó ti máa ń jẹ yọ. Ọrọ Asojúsòdìpọ Irúfẹ àwọn ọrọ wọnyí ni a tún lè pè ní ọrọ asèjì-èròpọ (a-so-èjì-èrò-pọ) tí wọn máa ń fi èrò mejì ọtọọtọ sí ẹgbẹ ara wọn ṣùgbọn tí èrò wọn lè má tèlé ara wọn tàbí kí wọn jẹ ojú àti òdì ara wọn. Àfi/àyàfi Èyí ni àwọn ọrọ tí a lè lò láti so èjì èrò pọ ṣùgbọn tí ó jẹ pé èrò tàbí gbólóhùn kejì gan-an ni a ń retí pé kí ó ṣe tàbí kó fìdí múlẹ kí èrò inú tàkọkọ tó lè wáyé. Ìyẹn ni pé, dandan ni kí gbólóhùn kejì ó ṣelẹ kí ti àkọkọ tó lè dúró. Gbólóhùn kejì ni èrèdí tàbí òté fún ìmúṣẹ gbólóhùn àkọkọ ní ibi tí a bá ti lo “àfi/àyàfi”. Yàtọ sí èyí, òdì ni gbólóhùn àkọkọ máa ń jẹ sí èkejì. Àpẹẹrẹ: 23a) Adébọlá kò níi lọ àfi/àyàfi bí ó bá rí Tolú ọrẹ rẹ b) Kò ní tẹlé ọ àfi/àyàfi bí ó bá rí ẹgbọn rẹ. d) Àwọn òṣìṣẹ kò ní padà sẹnu iṣẹ àfì/àyàfi bí ìjọba bá fún wa ní ẹkúwó e) Lọlá kò ṣetán láti rinsẹ àfi/àyàfi bí Tọlá bá máa lọ. A lè lo “àfi” ní ìbẹrẹ gbólóhùn láìsí gbólóhùn tí a so ó mọ ní ìbẹrẹ rẹ. Ṣùgbọn ó wọpọ láti máa lo “àfi” báyìí dáadáa ju “àyàfi” lọ. Àmọ, bí a bá lo “àyàfi” báyìí, yóò fún wa ní ìtumọ ìtẹnumọ ju ti “àfi” lọ. Àpẹẹrẹ: 24a) àfi bí o bá fẹ jẹ ẹran tútù b) àfi bí o bá fún mi ní owó mi. f.w. d) àyàfi bí ó bá fún mi ní owó mi. Àwọn òté tó de ìlò “àfi/àyàfi” tí a lè tọka sí ni • Òté àkọkọ tí ó de ìlò “àfi/àyàfi” ni pé, gbólóhùn àkọkọ gbọdọ jẹ òdì ti èkejì tí ó wà nínú ìhun tí ọrọ-àsopọ náà ń so pọ. • Òmíràn tún ni pé, gbólóhùn kejì ni èrèdí tàbí àtẹgùn fún ìmúṣẹ ohun tí ti àkọkọ ń sọ. Ìyẹn ni pé láì sí gbólóhùn kejì, ìjóòtọ èrò ti àkọkọ kò ṣe é ṣe. • Bákan náà, gbólóhùn kejì sábà máa ń bẹrẹ pẹlú “bí nǹkan bá rí báyìí”. Ìyẹn ni pé, “bí” jẹ atọka ìṣẹlẹ tinú gbólóhùn kejì. Àmọ àti Ṣùgbọn Àwọn wọnyí ni ọrọ a-so-èjì-èrò-pọ tí ìlò wọn wọpọ jù ní ìsọrí yìí. Kódà, nítorí pé wọn máa ń jẹ yọ pẹlú ìrísí wọn láàárín gbólóhùn méjì, àwọn méjèèjì ni àwọn onímọ kan ń pè ní ọrọ-àsopọ gbólóhùn. A lè lò wọn ní pàṣípààrọ láì ba ìtumọ gbólóhùn wọn jẹ. Èrò inú gbólóhùn àkọkọ máa ń jẹ òdì gbólóhùn kejì. Èrò méjì sábà máa ń jẹ alójúlódì tàbí aṣelòdì arawọn.